You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bùhárí: Gaddafi ló kọ́ darandaran ní ìwà ipá
Ààrẹ orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti dẹ̀bi itankalẹ awọn agbebon darandaran rú Aarẹ̀ àná lorílèèdè Libya, Muammar Gaddafi.
Buhari ṣàlàyé pe, Muammar Gaddafi lo kò awọn darandaran ní ìwà ipá, to sì kó òhun ija fún wọn.
Ọrọ naa jẹyọ nígbà to n ba Biṣoobu àgbà ìjọ Anglican, ẹ̀ni ọwọ Justin Welby, sọrọ ní London lọ̀jo ọjọ́rú.
O ní ìjọba òun n s'apa lati kojú ipenija aawọ darandaran àti àwọn àgbẹ eleyii ti àjọ ajafeto ọmoniyan kan lo ti gb'emi to ju ẹgbẹrun meji ló laipe yii.
Lọdun to kọ̀ja ni ìjọba Naijiria fòfin dè iferanje láwọn agbegbe kan, to sí ni ki awon eniyan maa fi ẹran ọsin sí pápá ijẹ̀ko.
Sugbọ̀n ọpọ èèyàn k'ọti ikùn sí àṣẹ yi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: