Rashidi Ladoja: Kí Bùhárí gbé àpótí ìbò wò, bóyá yóò borí
Published
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀rí, Rashidi Ladoja wípé kí àwon ọmọ Nàìjíríà jẹ́ kí Ààre Bùhárí gbé àpótí ìbò wò, bóyá yóò borí.
Ó ní ariwo gbalẹ̀ tẹ́lẹ̀ pé Bùhárí nìkan ló leè se Nàíjíríà dáadáa, sùgbọ́n lásìkò yìí, ojú gbogbo wa ti já a.
Ládọjà fikún u pé ààlà ni yóò fi oko ọ̀lẹ hàn, nígbà tó bá di ọjọ́ ìbò, níbití á timọ ẹnití ó lérò jù.