Ọga ọlọpa Naijiria pasẹ f'awọn ọlọpa to n sọ awọn oloṣelu lati pada sile

Ibrahim Idris

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Idris sọ wipe igbimọ amuṣẹya ti wa lati mu ki aṣẹ naa fidimulẹ

Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpa Naijiria, Ibrahim Idris ti pa laaṣẹ lọjọ Aje pe ki gbogbo awọn ọlọpa to n ṣiṣẹ ẹṣọ lọdọ awọn eeyan pataki lawujọ, to fi mọ awọn oloṣelu atawọn to di ipo iṣakoso mu jakejado orileede naa o kuro ni kiakia.

Idris to fi ikede naa sita nilu Abuja lasiko ipade ijiroro kan to ṣe pẹlu awọn lọga-lsga nileeṣẹ ọlọpa tọka si awọn ipenija to n koju eto aabo Naijiria gẹgẹ bi idi pataki fun aṣẹ naa.

Bakanna lo sọ wipe aṣẹ naa yoo tan de ọdọ awọn oniṣẹ adani, ileeṣẹ nlanla atawọn lajọlajọ mi i to n j'anfaani akanṣe eto aabo lati ileeṣẹ ọlọpa.

Lati mu ki aṣẹ naa mulẹ, Idris ni igbimọ amuṣẹya kan ti di fifilọlẹ loluleeṣẹ ajọ naa nilu Abuja labẹ iṣakoso adele kọmisanna ọlọpa, Mohammed Dankwara, nigba ti awọn kọmisaana to wa l'awọn ipinlẹ naa yoo ṣe bẹ nipinlẹ koowa wọn.

Igbesẹ pipe awọn ọlọpa to le ni igba ẹgbẹrun pada naa waye lẹyin ti awuyewuye waye lori bi ileeṣẹ ọlọpa ṣe ko pupọ ninu awọn oṣiṣẹ rẹ sọdọ awọn eeyan kan lawujọ, eyi to si n pa awọn ara ilu to ku lara.

Sugbọn nigba to n fi idi aṣẹ tuntun naa mulẹ fun ileeṣẹ BBC Yoruba, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpa ni Naijiria, Jimoh Moshhod ni awọn eniyan pataki ti wọn o fọwọsi laarin ilu nikan ni ofin tuntun yii kan.

Lori igbesẹ yi, Idris sọ wipe "oun yoo fi iwe ranṣẹ si aarẹ fun ibuwọlu. Eyi ti yoo si mu ki o duro bi ilana an tẹle lasiko ti wọn ba fẹ ko awọn ọlọpa lọ si ọdọ awọn eeyan gbajumọ ilu, oloṣelu atawọn mi to d'ipo oṣelu mu lorilẹede Naijiria.