AfCFTA: Awọn onimọ sọrọ lori ohun ti jijawọ Naijiria lee fa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alẹnulọrọ lẹka ọrọ ilẹ okeere ati idokoowo ti sọ wi pe igbesẹ ti aarẹ orilẹede Naijiria gbe lati jawọ kuro ninu adehun idokoowo ilẹ Afirika ku diẹ kaato.
Ninu iwoye wọn wọn woye wipe igbesẹ naa yoo ta abuku ba orilẹede Naijiria ni awujọ agbaye.
Ninu ọrọ to ba BBC sọ, onwoye isuna ati okoowo lagbaye kan, Bisi Iyaniwura ni lati ibẹrẹ lo ti yẹ ki orilẹede Naijiria mọ wi pe oun o ni eto ọrọ aje to duro deede lati fi se agbatẹru agbekalẹ adehun yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
" Lati ibẹrẹ ni ọrọ naa ti wọ wa. ọrọ aje orilẹede naijiria ko tii duro to lati gbe ojuse ti orilẹede Naijiria fẹ gbe lori adehun naa.
Awọn ohun amayedẹrun bii ina ati bẹẹbẹẹ lọ ko duro deede. Bẹẹni awọn ilana ijọba gbogbo ko se koriya fun idokoowo. Ilana ele lori owooya lorilẹede Naijiria lo fẹrẹ le kenka julọ ni ilẹ Afrika. Lootọ Naijiria ni ọja to pọ sugbọn eto ọrọ aje rẹ ko gbe"
Ọgbẹni Iyaniwura ni lootọ ni awọn orilẹede bii kenya, Ethiopia ati South Africa ni eto ọrọ aje to dara ju ti Naijiria lọ eyi si tumọ si wi pe awọn orilẹede wọnyi ni yoo maa janfani ọja to fẹ lorilẹede Naijiria.
O ni ohun to dara ni pe orilẹede Naijiria jawọ 'boya nitori pe o ti yee pe ọrọ aje rẹ ko lee duro ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu awọn orilẹede yooku ninu adehun naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
" Ohun ti o yẹ fun orilẹede yii ni pe ko si bi o se lee kopa to jọju ninu eto idokoowo agbaye pẹlu bi nkan se ri pẹlu ẹka osisẹ rẹ ati gbogbo ẹka ọrọ aje rẹ."
Ẹlomiran to tun ba BBC sọrọ ni Ọgbẹni Adetokunbọ Mumuni ti ajọ to n tọpinpin ọrọ aje ati idagbasoke ilu, SERAP to ni ireti ohun ni wipe "ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti gbe atunbọtan igbesẹ rẹ naa yẹwo lati mọ boya ko ni pa ọjọ iwaju awọn ọmọ orilẹede Naijiria lara."
Amọsa, ileesẹ aarẹ orilẹede Naijiria ni ariwo ati atako lati ọdọ awọn ẹgbẹ osisẹ, ẹka idokoowo lo sokunfa bii aarẹ se jawọ ninu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbẹnusọ fun aarẹ, Fẹmi Adesina, ni ipinnu yii ko pẹ ju sugbọn o tọ ki aarẹ jawọ ni ọrọ naa bayii nitori aifọwọ sii awọn alẹnulọrọ ju ko tẹsiwaju laisi atilẹyin wọn.
"Idi ti aarẹ fi jawọ ni lati duro de igba ti ijiroro gbogbo yoo mu ki awọn ẹgbẹ osisẹ ati ẹka idokoowo o se ohun to tọ.
Ohun ti awọn osisẹ n sọ ni wi pe yoo se ijamba fun a wọn ileesẹ to sẹsẹ fẹ gberu labẹle eleyi ti yoo lee mu akoba ba isẹ awọn osisẹ nibẹ"












