Orilẹede Pakistan, Iran ati Indonesia pẹlu awọn ilu ti ko fẹran ọjọ ayajọ ololufẹ
Awọn alasẹ orilẹede Pakistan, Iran ati Indonesia - awọn ilu tiko fẹran ọjọ ayajọ ololufẹ sọ wipe ọjọ naa n sẹ igbelarugẹ fun asa ajoji lawujọ wọn.
Ni India, awọn eniyan ma n se ayajọ yi sugbọn awọn ẹgbẹ oloselu kọọkan bu ẹnu atẹ lu ayajọ ọjọ ololufẹ.