You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
N kò nílò ọtí tàbí sìgá kí n tó wa ọkọ̀ ńlá Tírélà bí àwọn yòókù- Ademola Taiwo
Arabinrin Ademola Taiwo Omolade ni oun yatọ si pupọ awọn akẹgbẹ oun ti wọn nilo lati mu ọti tabi siga saaju ki wọn to gbe Tirela soju popona.
Omolade ba ileeṣẹ BBC News sọrọ lori irinajo rẹ sinu isẹ awakọ Tirela, eyi to ti sọ di ilumọka lori ayelujara.
O ni ko ki se pe isẹ awakọ tirela deede wu oun sugbọn irinajo naa bẹrẹ nigba ti oun wa lọdọ ẹgbọn oun, ti ọkọ ẹgbọn rẹ to jẹ awa-tipa, si gba lati maa mujuto ileeṣẹ Tipa to dasilẹ.
"Mo sọ fun ọkọ ẹgbọn mi pe n ko se alamojuto, pe mo fẹ kọ wiwa ọkọ tirela yii ni.
"Mo ni ọrẹ kan, oun lo mu mi lọ si ọdọ ọga mi to kọ mi ni isẹ
"Ọpọ awọn eeyan lo bu ẹnu atẹ lu bi Ọga mi se gbe iru mọto nla naa fun obinrin, to tun wa jẹ ọmọde.
Mo dupe lọwọ Ọlọrun pe lati igba ti mo ti bẹrẹ si ni wa Tirela yii, n ko ri ijamba ri:
Omolade tẹsiwaje pe bi oun se ọkọ Tirela naa ko sẹyin Ọlọrun to n fun oun se, ti ko jẹ ki oun ri ijamba.
O ni oun ko ri isẹ naa gẹgẹ bi ohun to nira, nitori o jẹ ohun kan to ti mọ ohun lara pupọ.
"Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe n ko kọlu eeyan bakan naa ni wọn ko kọlu mi.
"Inu awọn Ọga mi maa dun simi nitori mo peyeke ju pupọ awọn ọkunrin ẹgbẹ lọ.
"Bakan naa ni n ko ki mu ọti tabi siga saaju ki to wa ọkọ mi."