Taiwo Awoniyi, Nottingham Forest, Sport: Ìlú Oyìnbó kò rọrùn ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ ibi tí orí, Olúwa, ẹbí àti ará gbé mi dé báyìí

Mo kọ̀ láti gbàgbé ilé àti orísun mi ni mo ṣe padà wá n pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ ní Ilorin,

Taiwo Awoniyi Michael lo jẹ ojulowo ọmọ Naijiria to n gba bọọlu fun Nottingham Forest ni England to dide lati Ilorin ni ipinlẹ Kwara ni Naijiria lati maa gba bọọlu lati ọmọ ọdun meje.

O ni oun mọọmọ n pada wa si Ilorin lati wa fi imoore han fun orisin oun ni.

Taiwo Awoniyi sọ nipa awọn idojukọ rẹ ko to moke ninu bọọlu gbigba.

O sọ bi o ṣe maa n fi ẹsẹ rin lati adugbo Agboọba fun wakati kan o le ko to de ori papa to ti n kọ bọọlu gbigba.

O gba awọn ọdọ nimọran lati ni suuru ki wọn si ṣọra ki enikeni ma fi ilu oyinbo tan wọn jẹ.