You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Postpartum Depression Ìrírí ìrẹ̀wẹ̀sí ọkàn lẹ́yìn ìbímọ ló jẹ́ kí n pinnu láti ran àwọn obìnrin míì lọ́wọ́- Opeyemi Lawal
Aisan to n ṣe alaboyun lẹyin ibimọ ni oloyinbo n pe ni ''Postpartum Depression.''
Oṣiṣẹ ilera taa ba sọrọ lori aisan to n koju alaboyun lẹyin ibimọ,arabinrin Opeyemi Lawal yannana awọn ewu to wa nibi aisan yi.
Ṣaaju o ṣapejuwe awọn apẹrẹ ti wọn a maa ri lara alaboyun.
Ninu rẹ lo sọ pe lọpọ igba ti alaboyun ba dakẹ ti ko ba eeyan sọrọ lẹyin to bimọ tabi to n sunkun, o to ki eeyan fura si i.
Ni igba talaboyun ba bimọ nikan si kọ ni a le ri apẹrẹ yi.
O ni 'ṣaaju ki wọn to loyun, nigba ti wọn ba loyun ati lẹyin ti wọn ba bimọ''ni awọn apẹẹrẹ yi maa n foju han.
Eeyan kan laarin alaboyun marun un ni akọsilẹ wa lagbaye pe yoo koju iru ipenija yi.
Aisan yi a maa koju awọn alaboyun lẹyin ti wọn ba bimọ ṣugbọn wọn a tun maa koju rẹ ṣaaju ki wọn to bimọ.
Ṣebi wọn ni ti eeyan ba bimọ inu rẹ maa n dun ni?
Ninu akawe ohun tioju rẹ ri nigba to bimọ, arabinrin Opeyemi sọ pe iṣẹ abẹ ni wọn ṣe fun oun lasiko ibimọ.
O ni eyi kọkọ yatọ si ero ọkan rẹ pe oun yoo bimọ lalae ṣe iṣẹ abẹ.
''Wakati mẹrinlelogun ni mo fi wa lori idubulẹ lẹyin ti wọn pari iṣẹ abẹ.Koda bi wọn ṣe gbe ọmọ funmi, ara ṣi n ro mi.
O tẹsiwaju pe ''Mo wa ni inu inira ti mi o si gbọdọ dide lati gba ọmọ naa bi wọn ṣe gbe han mi''
- Àsìkò wo ló yẹ kí obìnrin bẹ̀rẹ̀ ìbálòpọ̀ padà lẹ́yìn ìbìmọ láìséwu?
- 'Ó dùn mí jù pé n kò rí ọmọ mi fún ọdún kan torí ikọ́ fée ti mo ní'
- Mọ̀ síi nípa ewu tó rọ̀ mọ́ níní ìbálòpọ̀ lásìkò ìlóyún lórí ètò Sé lóòtọ́ ní BBC
- Níbo lẹ ti gbọ́ pé mo kọ ọkọ mi sílẹ̀ ló fẹ́ Pasuma?, Bí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ èmi àti Paso ṣe bẹ̀rẹ̀ rèé- Jaye Kuti
Opeyemi ni bawọn ṣe pada de ile lẹyin ibimọ loun ṣe akiyesi pe oun ko nife si ounjẹ jijẹ.
''Nigba miran ti mo ba sun, mo maa ri irikuri loju orun.Sebi wọn ni ti eeyan ba bimọ inu rẹ maa n dun ni?''
'' Bi wọn ba beere ọrọ lọwọ mi, niṣe ni omi maa n da loju mi pẹrẹpẹrẹ.Igba mii maa kọ ẹgbẹ kawọn eeyan ma ri pe mo n dami loju''
- Adé tó ń dán gbiirin tí yóò sọ Charles Phillip Arthur George di Ọba
- Ó jọ àwọn èèyàn lójú bí mo ṣe ń fi èdè Yorùbá kọ́ -Mathematics- lorí ayélujára - Tísà Hakeem Adeniyan
- Kìí ṣe pé mo yí orin padà sí ti Ọlọ́run, ìyàtọ́ orin mi ti tẹ́lẹ̀ sí ìpè -Evangelist- ti mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà rèé - Ebenezr Obey
- Wo ọmọ Nàìjíríà tó ṣe ọkọ̀ ìdíje ‘Formular 1 race car’ àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà
Iriri mi lẹyin ibimọ lo jẹ ki n sọ pe ki n maa ran awọn obinrin mi lọwọ
Pẹlu atilẹyin ọkọ rẹ,arabinrin Opeyemi pada tujuka to si wa pinnu lati ran awọn obinrin miran to ba ni iru ipenija bayi lọwọ.
O lo anfaani pe o n ṣiṣẹ ni ẹka iroyin lati maa ba awọn obinrin sọrọ nipa iriri rẹ yi.
O ṣalaye pe pupọ awọn obinrin toun ba sọrọ ni o ṣe awọn naa ri ṣugbọn awọn paa mọra ni.
Nipa igbiyanju rẹ, o ti n mu ki ọpọ mọ nipa ipenija yi ti o si ti n jẹ ki o rọrun lati sọrọ nipa rẹ.
u