Okafor Nkechi Agness: Ẹbí kọ̀ mi sílẹ̀, Bàbá mi kú lórí wàhálá mi ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti tọrọ bárà

Omọ Igbo ni mi ṣùgbọn Ekiti ni wọn bi mi si ni mo fi gbọ ede Yoruba daadaa.

Okafor Nkechi Agness lo gbalejo BBC Yoruba nibi to ti ri oore ọfẹ lati sọ nipa irinajo aye rẹ lati kekere.

O sọ nipa ala rẹ lati ṣoju Nijiria ninu idije ere sisa gbogbo lati kekere rẹ ko to di pe o ṣaisan nigba kan ti ẹsẹ si kọ alti ṣiṣẹ mọ.

O ṣalaye ohun ti oju Obi rẹ ri ki Baba rẹ to re ibi agba n re ati ibi ti ọrọ rẹ de duro.

Agness sọ bi oun ṣe ronu lati pa ara oun ni akoko kan ki aanu Olodumare to sọrọ lori aye oun.

O gba awọn to ni ipenija kankan ni ara wọn ni iyanju lati maṣẹ gbe igba bara ṣugbọn ki wọn ni afojusun ot dara ati oju inu lati wadi talẹnti ti Olodumare fi jinki koowa.