Mike Abdul Midnight Crew: Ìdí tí mo fi fẹ́ràn Fuji rèé – Olórin ẹ̀mi

Gbajugbaja olorin ẹmi Mike Abdul to gbajumọ fun wiwa lara awọn ẹgbẹ olorin ẹlẹni mẹrin kan ti gbogbo wọn n jẹ “Midnight Crew” ti fesi si awọn to n bu ẹnu atẹ lu awọn olorin ẹmi to n lo oniruuru ijo ati ilu igbalode fi fa oju awọn ọdọ mọra.

Mike Abdul n sọ ọrọ pẹlu idunu ati ayọ lori ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba ti inu rẹ si n dun bi oun atawọn akẹgbẹ rẹ ṣe yan lati maa lo nkan tawọn ọdọ ti ko fẹ sunmọ Ọlọrun fẹran lati fi fa oju wọn mọra.

“Olorin ẹmi ni mi, mo fẹran lati maa kọ ọrọ orin. Tẹẹ ba kọ nkan to yẹ kawọn eeyan maa gbọ fun wọn, wọn o ni ṣe nkan to yẹ ki wọn ṣe”.

Mike ṣalaye pe ile ẹkọ giga YabaTech ni oun atawọn toku oun ti pade ti wọn si rii pe imọ wọn jọra ninu kikọ orin, bi wọn ṣe bẹrẹ niyẹn ti ọpọlọpọ eeyan si fẹran ẹgbẹ Midnight Crew.

“A pade ninu ẹgbẹ nla mii taa ti maa n lọ kọrin nile ẹkọ ti wọn n pe ẹgbẹ naa ni “Original Love Choir”, ibẹ la ti n sọ pe mo fẹran bi ẹni yii ṣe n kọrin, baa ṣe mu ara wa niyẹn”.

O ni ayanmọ lo mu awọn papọ amọ bi awọn ṣe ṣetan nile ẹkọ, wọn jọ joko pe ṣe bi yoo ṣe pari niyi, wọn wa ni ki awọn gbe orin awọn wọ inu aye lọ, bi gbogbo wọn ṣe bẹrẹ niyẹn.

Ki lo ṣẹlẹ ti ẹgbẹ olorin Midnight Crew tuka?

Mike Abdul tun tan imọlẹ si ohun to faa ti iyapa fi wa laarin oun atawọn to ku rẹ.

O ni kii ṣe pe awọn yapa ni ti ọta ara ẹni rara, koda wọn a maa pe ara wọn kiakia nigba mii pe “iwọ mu orin wa, iwọ fi ohun kọ orin yii fun mi” ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Mike Abdul ni Yoruba yẹn le o, “tuka yẹn dabii pe eeyan ja, amọ awa o ja tuka”.

O ni awọn kan pe ara awọn jọ ni pe, awọn ti n lo bii ọdun mẹwaa papọ o, nkan si ti n yi pada, ọkọ awọn obinrin awọn naa yoo maa nilo wọn ju ti ẹgbẹ lọ tori naa lawọn ṣe jọ “gbimọ pọ ni” lati ni “ero ọtọọtọ (Individual expression).

Nipa lilo FUJI fi kọrin ẹmi

“Mo jẹ eeyan kan to maa n ni nkan ṣe pẹlu awọn ọdọ gidi gan mo si ti di ara wọn, iyẹn lo jẹ ki n fẹran FUJI”.

O ni bi igba ti awọn oyinbo naa ba n fi ọrọ taka ni oun fẹran ti oun ba ri awọn ọdọ ti wọn n daṣa.

O ṣalaye pe Fuji tawọn olorin ẹmi n fẹnu tẹmẹlu gaan lo jẹ aṣa tiwa, ilu Highlife kii ṣe tiwa.