Sanni Iyabo Paramount Komedy: Ibi tí mo ti rí àwọn ọfọ̀ apanilẹ́rìín tí mò ń lò nínú 'skit' nìyí

"Kii ṣe ipanilẹrin tẹẹ mọ mi mọ gangan ni mo fẹ ṣe, mo kan n loo lati ṣi ọna fi wọ inu agbo ere Tiata ni".

Paramount Komedy gangan lẹ mọ ọ si amọ orukọ rẹ gangan ni Sanni Iyabo o si jẹ ọkan lara awọn irawo to n dide lagbo awọn adẹrinpoṣonu ati pe o jẹ oṣerebinrin.

Bakan naa ọdọbinrin yii jẹ eeyan to ti fa oju ọpọlọpọ mọra latoju opo ayelujara pẹlu gbogbo ẹfẹ rẹ.

Ọmọ ogun ọdun o le diẹ ṣi ni PAramount Komedy to n mi ori ayelujara titi pẹlu awọn ẹfẹ tawọn eeyan fẹran.

Ọmọ bibi ipinlẹ Ogun ni Iyabo o si ba BBC Yoruba sọrọ lori idamu ohun laalaa to la kọja laye rẹ ko to yi biri to di ẹni tawọn eeyan bẹrẹ si ni yẹ si ni nkan bii ọdun diẹ sẹyin.

Fasiti Tai Solarin nipinlẹ Ogun lo ti pada kawe gboye ninu imọ tiata lẹyin ọpọlọpọ igbiyanju lati pari ẹkọ rẹ nile ẹkọ giga gbogbo niṣe to ti kọkọ bẹrẹ..

Paramount ṣalaye pe igba ewe ati ọdọ oun ko dan mọran rara tori ko si ohun agbaye gbadun kankan ti ẹbi oun ni lasiko naa gẹgẹ bii atapata-dide.

Amọ o sọ bo ṣe tiraka lati maa ta awọn nkan pẹpẹpẹ ati ṣiṣe iṣẹ lawọn ileeṣẹ kan ko le fi ran ara rẹ nile ẹkọ.