You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Plastic Recycler: Asade Abdulsalam ni kìí ṣe gbogbo ìdọ̀tí ni ẹ̀gbin, owó ni
Ori lo mọ isẹ asela, inu ẹgbin si ni ọla n gbe.
Ọkunrin kan ree, Asade Abdulsalam Abiodun to yan isẹ saatan dọrọ laayo, to si n fi ike sisa kiri loju popo jẹun.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Asade ni asise gbaa ni ero awọn eeyan to ro pe gbogbo idọti lo jẹ ẹgbin.
- Máṣe rí ẹ̀gbin ní àyíká rẹ mọ́, sọ ààtàn d‘ọrọ̀ láti pawó ńlá wọle
- 'Ike N15,000 tàbí N10,000 ni mo ń ṣa fún owó iléèwé àwọn ọmọ'
- Ẹ̀kún l'oúnjẹ́ mi ní ọ̀pọ̀ ìgbà lẹ́yìn tí ojú mi fọ́ ní JSS 3- Lawal Ayankemi
- Báàgì Ghana Must Go pàwọ̀dà, ó di ohun táwọn ránsọ ránsọ fi ń dárà orísirísi
- Ọ̀rá ‘Pure Water‘ àti àlòkù aṣọ ni mo fi ń ṣe aṣọ òkè láti pèsè ohun mère-mère - Adejoke Lasisi
- Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé ìdọ̀tí rẹ le è sọ ẹ́ di olówó?
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ arábìnrin tó fẹ́ ta alòkù kọ́ńdọ́ọ̀mù 324,000 padà f'áwọn èèyàn
- Kíni ìdí tí wọn fẹ́ fòfin de lílo ọ̀rá nylon ní Naijiria?
- '3% ahọ́n bàbá mi lagbébọn fọ́ pátápátá! Àwọn Dókítà India ní ká lọ mú 30,000 Dollars wá'
O salaye pe igi owo gbaa ni ọpọ idọti to wa lawujọ wa, to si kede pe ọpọ anfaani lo wa ninu isẹ naa.
Wọn ro pe mo ti ya were, ni mo se n sa idọti kiri ladugbo:
Asade salaye pe ọpọ eeyan lo korira oun nigba ti oun bẹrẹ isẹ naa, ti wọn si lero pe oun ti ya were ni oun se n sa awọn ike naa kiri adugbo.
O salaye pe oun ni ẹgbẹ kan, to wa fun imọtoto ayika, ti awọn ọdọ to jẹ ọmọ ẹgbẹ naa yoo si maa gba ayika kiri lati palẹ idọti mọ.
Nigba to ya, lo ni oun bẹrẹ si ni yọ awọn idọti to jẹ ike lasan si ẹgbẹ kan, ti oun si n ta lati ri taje se.
Lọwọ lọwọ bayii, Asade ti ni ileesẹ kan to n pa awọn ike naa si pẹlẹbẹ, ti yoo si ta wọn fun awọn oyinbo lati fi se ohun meremere.
Anfaani to wa ninu sisa ike kiri adugbo:
Asade mẹnuba ọpọ anfaani to wa ninu bi awọn se n sa ike kiri loju popo naa.
O ni awọn ike tawọn n sa yii ni yoo se agbelarugẹ idena biba ayika jẹ, paapaa nibayii ti ayipada n ba oju ọjọ jakejado agbaye.
Bakan naa lo ni ike tawọn n sa kiri naa ni yoo mu adinku ba idọti loju popo, ti yoo si dena isẹlẹ ẹkun omi lagbegbe awn.
Awọn idọti ti wọn n sa kiri naa lo tun n mu owo wa fun wọn, to si n ta eroja naa fawọn oyinbo lati fi se awọn eroja to wulo ni awuja.
Asade ni lara awọn ohun meremere ti wọn n lo awọn ike ti wọn sa naa fun ni bata, asọ, tabili ounjẹ ninu ile, igi keresimesi ati awọn ohun aramọnda miran.
Ko tan sibẹ, Asade tun ni oun ni awọn osisẹ to n sisẹ fun oun, ti wọn n seranwọ lati se itọju ike naa, ti awọn to n sa ike kiri oju popo ba ko de.
Gbajumọ saatan dọrọ naa wa ke sawọn araalu pe ki wọn dẹkun fifi oju abuku wo awọn eeyan to n sa ike kiri oju popo nitori igi owo ni wọn.