12 year old girl killed in Ondo: Nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ni mo bá a ní òwúrọ̀ kùtùkùtù - Bàbá

Ọmọ ọdun mejila kan, Goodness Duduyemi ni wọn ti gun pa ninu ile awọn obi rẹ ni ipinlẹ Ondo.

Iṣẹlẹ ọhun ni ile iṣẹ iroyin BBC News Yoruba gbọ pe o ṣẹlẹ ni ilu Igbara-oke ni ijọba ibilẹ Ifedore.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo ni ipele oniwe kẹta nile ẹkọ girama ni ọmọ naa wa ni ile-ẹkọ alaadani kan ni ilu Igbara-oke ki wọn to da ẹmi rẹ legbodo ni ọsẹ to koja.

Iroyin sọ wipe ọna maarun ni wọn ti gun Goodness nibi to sun si ninu ile baba rẹ ni adugbo Adepoju-Daramola.

Bo ti lẹ jẹ pe awọn obi rẹ ko fẹ ba BBC sọrọ, awọn ara adugbo sọ pe oru mọju ni awọn ẹni ibi yii ṣiṣẹ ika naa.

Lẹyin ti wọn ti sin ọmọ naa ni baba rẹ lọ fi ọrọ lọ awọn ọlọpa.

Iṣẹlẹ naa ti da ẹbi, ati ara adugbo si inu ọfọ ti wọn si juwe ọmọ ọhun gẹgẹ bi ọmọ to ṣee mu yangan.

Alukoro ajọ ọlọpa ni ipinlẹ Ondo Funmilayo Odunlami sọ pe baba Goodness, Duduyemi Emmanuel lo wa fi ọrọ naa lọ ni agọ ọlọpa lẹyin iṣẹlẹ ibanujẹ naa.

Odunlami ni pe Duduyemi ṣalaye pe oun ba ọmọ oun ninu agbara ẹjẹ lẹyin ti oun gbọ ariwo rẹ lati oju orun ni bi aago mẹrin owuro kutu pẹlu ami gigun nibi maarun ọtọọtọ.

Alukoro naa ni pe baba ọmọ naa ni oun ṣe akiyesi pe ilẹkun abawọle ẹyin si yara igbalejo ati ile idana wa ni ṣiṣi silẹ lẹyin iṣẹlẹ yii.

O ni pe wọn gbe Goodness digba-digba lọ si ile-iwosan amọ ẹpa o boro mọ.

Odunlami wa fi da awọn ebi oloogbe ati ara ilu loju pe iwadi ti bẹẹrẹ lori iṣẹlẹ naa lati ri i pe ọwọ ofin tẹ awọn to ṣiṣẹ ibi yii.