MTN service outage: Iléèṣẹ́ MTN tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ àwọn oníbàárà fún ojú òpó wọn tó dẹnukọlẹ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ, MTN Nigeria ti tọrọ aforiji lọwọ awọn onibaara rẹ ti ko ri oju opo naa lo lasiko yii.

Wọn fi ikede naa sita ni oju opo Instagram wọn ni irọle ọjọ Abamẹta lẹyin wakati diẹ ti awọn onibaara wọn ko ti le pe tabi gba ipe lori siimu MTN wọn.

Bakan naa ni atẹjiṣẹ naa ko lọ, ti oju opo ayelujara naa ko si ṣe e ṣi.

Ninu ikede ti MTN fi sita, wọn ni awọn tọrs aforiji fun inira yoowu ti oju opo to daku naa n fa.

Botilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ko sọ nkan to fa idaamu naa, wọn ni awọn ti n ṣiṣẹ lori ọna abayọ.

Ohun to ṣẹl si MTN yii waye lẹyin ọjọ diẹ ti oju opo ibaraẹnidọrẹ Facebook, Instagram ati Whatsapp dẹnukọlẹ kaakiri agbaye.