Ọ̀pẹlọpẹ́ Ajá tí Ifa ní kí a fi ṣètùtù ní Ekiti ní 1942 ni kò jẹ́ kí ìjàmbá náà pọ̀ jù- Oloye Olu Adeniji

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ba BBC Yoruba sọrọ ni kikun.

Ojọ kejila, oṣu kẹrin ọdun 1942 ni baalu ọkọ ofurufu akọkọ ja ni ilu Ikogosi, ni ipinlẹ ekiti ni guusu Iwọ oorun Naijiria ni iwo oorun ilẹ Adulawọ.

Eyi ni ọkọ baalu akọkọ ti yoo ja ni ilẹ Adulawọ lapapọ.

Iru rẹ ko ṣẹlẹ ni ri ni Naijiria pẹlu.

Nkan ogun ni ọkọ baalu naa n ko nitori pe lasiko ogun lagbaye lo ṣẹlẹ.

Oloye Olu Adeniji ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ni 1942 ṣalaye fun BBC Yoruba pe ọkọ ofurufu Germany ni baalu na to ja.

O sọ nipa bi ẹru ṣe ba gbogbo ara ilu lasiko naa.

Faleye Babatunde Samuel to jẹ olori ọdọ ni Ikogosi naa ba BBC sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

Oun naa ni ori oke Aeroplane ni awọn n pe ibi to ti ṣẹlẹ yii.

Oke Ilapa ni awọn ara ilu n pe ibẹ ṣaaju iṣẹlẹ naa.

Ipa wo ni Aja ko ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ ofurufu naa?

Oloye Olu Adeniji salaye ipa pataki ti aja ko lati doola ẹmi awọn ara Ikogosi ninu ijamba ọkọ ofurufu ọdsun 1942 naa.

O ni Babalawo to n difa ojoojumọ ladugbo lo kọkọ rii pe nkan maa ṣẹlẹ ni Ikogosi to lagbara.

O ni Ifa naa jade pe laarin ọjọ meje ni nkan ti ko ṣẹlẹ ri a ṣẹlẹ ni Ikogosi ni ẹru ba n ba gbogbo ara ilu.

Adeniji ni nigba ti wọn beere ọna abayọ ti ko fi ni mu ẹmi dani ni Ifa ni ki wọn mu aja kiri ilu naa ki wọn dẹ fi setutu kaakiri ikogosi.

O ni eyi ni ọpọ gba pe o jẹ ki ọkọ ofurufu naa lọ jasi ori oke naa laipa awọn eeyan lara ni alẹ ọjọ keje ti Ifa sọ.

Awọn eeyan inu ọkọ ofuruf naa n kọ?

Oloye Adeniji ṣalye fun BBC pe lẹyin ti ọkọ ofurufu yii pada jabọ lẹyin to gbina to da ọpọlọpọ ọta ati nkan ija sita tan lo sun de ibi to wa.

O ni nigba naa ni awọn ọdẹ ilu ati ọlọpaa kan ṣoṣo to wa ni ẹkun Ekiti nigba naa lọ sibẹ.

Koda, o ni baba oun atawọn mii lo ko ẹran ara awọn oku ti wọn ri ti wọn si lọ sin wọn.

Ojọ nla ni ọjọ Eti, ọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun 1942 ti iṣẹlẹ malegbagbe yii ṣẹlẹ ni Ikogosi.

Adeniji ni o yẹ ki wọn gboriyin fun awakọ ofurufu naa nitori ẹẹmẹta lo pooyi yi ilu ka to n wa ibi to maa balẹ ojiji si ni pajawiri ki nakn to ṣẹlẹ to waye.