You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lagos Lion: Ó di dandan kí ará India yìí sọ ìdí tó fi ń sìn kìnìhún- Egbeyemi
Awọn oṣiṣẹ alatunṣe agbegbe ni ìpínle Eko, Lagos Environmental Sanitation & Special Offences ti dé si ilé ọkùnrín India to n sin kinihun ni V.I.
Bawo ni ọrọ kinihun yii ṣe jẹ? àti pe Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé Cameroon ni wọ́n ti ru Kìnìhún VI wá?
Arakunrin India ni wọn no o gbe kinihun yii wole ni ojule 229, adugbo Muri Okunola ni Victoria Island.
Saaju ni wọn ti kọkọ kọwe si ajọ to n mojuto atunṣe agbegbe ati awọn iṣẹlẹ ọdaran to yatọ iyẹn Lagos State Environmental Sanitation & Special Offences (Enforcement Unit) LASESSO.
Lati ọjọ Eti ni ajọ LASESSO ti wa ni iwaju ile ọkunrin ara orilẹ-ede India ti wọn ni o n sin kinihun yii.
Ogbéni Yinka Odeyemi to jẹ adari wọn ṣalaye pe kọmiṣọnna fun ọrọ awujọ ati iṣẹ agbẹ ti fun wọn laṣẹ lati gun kinihun naa ni abẹrẹ to maa gba agbara rẹ loni.
Ni eyi to ti wa si imuṣẹ bayii.
Bayii wọn ti gbe kinhun naa lọ si ọgba eranko ni Omu ni Bogijẹ ni Lekki.
Ogbeni Egbeyemi ti ni arakunrin India yii ni lati wa wi tẹnu rẹ lori ọrọ kinihun naa to sọ di ẹran ọsin ile laarin igboro.
- Kíni àwọn ìpèníjà ẹtọ ààbò ṣáájú òmìnira Nàìjíríà?
- Kunle Afolayan, òṣìṣẹ́ báńkì tẹ́lẹ̀ kó tó di gbajúgbajà òṣèré
- Àwọn mẹ́rin t'íjọba Buhari k'etí ikún s'àṣẹ òmìnira iléẹjọ́ lórí wọn rèé
- Àwọn ọmọ ilẹ Indonesia ṣe ìwọ́de lóri fífòfin de ìbalòpọ ṣáájú ìgbéyàwó
- Ìran tí Primate Ayodele rí ṣáájú ìdìbò Kogi àti Bayelsa rèé!