Báyìí ni àwọn alátìlẹ́yìn Super Eagles ṣe ń dá músò ṣáájú ìdíje tòní

Ẹgbẹ alatilẹyin ikọ Super Eagles lorilẹede Egypt n fi idunu wọn han pe ifẹsẹwọnsẹ oni yoo ṣẹnu 're fun Nàìjíríà.

Ẹgbẹ alatilẹyin Super Eagles
Àkọlé àwòrán, Ajọyọ yii ko yọ awọn ara orilede Egypt ti wọn jẹ ọrẹ awọn ọmọ Naijiria to wa lọhun. Ṣe ni baba oyinbo naa gbe apa ijo gẹngẹ.
Ẹgbẹ alatilẹyin Super Eagles
Àkọlé àwòrán, Lati alẹ́ ọjọ Ẹti lawọn ẹgbẹ́ alatilẹyin ikọ Super Eagles(Supporters Club) ti n fi orin ati ilu ṣatilẹyin fun ẹgbẹ agbabọọlu Nigeria ṣaaju ìfẹsẹwọnsẹ oni pẹlu Cameroon.
Ẹgbẹ alatilẹyin Super Eagles
Àkọlé àwòrán, Tọkunrin tobinrin lo ṣe ajọyọ lagbo faaji tori wọn ni awọn ti fi ohun gbobo le Oluwa Eleduwa lọwọ
Ẹgbẹ alatilẹyin Super Eagles
Àkọlé àwòrán, "Onilu yii ma pa mi o, owo rọọbu ti wọn. Maa kan mi nibadi ki n to deleee..."
Ẹgbẹ alatilẹyin Super Eagles
Àkọlé àwòrán, Lagbo faaji awọn ọmọ Naijiria to n ṣe ajọyọ ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ Naijiria ati Cameroon.
Ẹgbẹ alatilẹyin Super Eagles
Àkọlé àwòrán, Oke oke lẹyẹ nlọ o ni adura ti awọn ololufẹ Super Eagles ni Egypt fi bọ ẹnu ni idunnu si abajade esi ifẹsẹwọnsẹ tonii.
Ẹgbẹ alatilẹyin Super Eagles
Àkọlé àwòrán, O yaaa! gbera! gbẹsẹ! gbé bọ́dì ẹ̀!
Ẹgbẹ alatilẹyin Super Eagles
Àkọlé àwòrán, A o ni gba ọjẹgẹ rara ninu atilẹyin wa fun ikọ Super Eagles