Tsunami: Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ti Jumasil ti sọnù ni wọ́n rii padà
Iyanu nla, ọmọ to sọnu ti wọn gba pe o ti ku pada wale.
Erekuṣu Sulawesi ni orilẹ-ede Indonesia ni Tsunami ti gbẹmi ọpọlọpọ eniyan lai yọ ọmọ wẹwẹ silẹ.
Jumasil ni ọmọ ọdun marun un ti wọn gbà pé o ti ku sinu iṣẹlẹ ijamba Tsunami to ṣẹlẹ ni Indonesia.
Lẹyin ti àwọn obi rẹ ti wa a fun ọpọlọpọ ọjọ laarin awọn oku àti alaaye to farapa nile iwosan ti wọn ko rii.
Ni wọn wa gba pe o ti ba iṣẹlẹ Tsunami naa rin nigba ti o n ṣere letido ni eyi ti wọn fi gba kámú sí.
Ori ẹrọ ayelujara lo pada ṣe atọna bi wọn ṣe ri Jumasil nigbẹyin ti o si pada sile lọdọ iya rẹ.
Iya rẹ ni latigba to ti de pada sile ni ẹ̀rù nkan to ṣẹlẹ sii ti n baa ti o n so mọ oun rin kiri.Link
O le ni ẹgbẹrrun meji eniyan to gbẹmi mi lori ọrọ Tsunami naa ni eyi ti wọn sin wọn papọ.
Ọpọlọpọ ẹbi ati iyekan ni iyapa de ba ṣugbọn laipẹ ni awọn eeyan n ri ara wọn pada pẹlu ayọ.