''Àdúrà ni ọ̀pọ̀ aláwọ̀dúdú l'Amẹrika ń gbà pé kí ẹgbẹ́ òṣèlú Democrat wọlé aṣòfin''

Àkọlé fọ́nrán ohùn, ''Àdúrà ni ọ̀pọ̀ aláwọ̀dúdú l'Amẹrika ń gbà pé kí ẹgbẹ́ òṣèlú Democrat wọlé aṣòfin''

Awọn ọmọ ilẹ Amẹrika kan ti wọn jẹ alawọdudu ni wọn salaye pe Aarẹ ilẹ Amẹrika Donald Trump n fi aye ni awọn lara lorilẹede naa.

Ọkan ninu wọn to ba BBC Yoruba sọrọ Fatima Gbenla sọ pe oju awọn ọmọ ilẹ Amẹrika ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Afirika tabi alawọdudu n ri mọbo.

Bẹẹ naa ni ẹlomiran to tun ba ile isẹ BBC sọrọ Sola Longe ni Aarẹ Trump ko ni le tẹsiwaju pẹlu igbesẹ rẹ lori ofin to ti pinnu fun awọn alejo ti ẹgbẹ oṣelu Democrat ba wọle ninu idibo ile aṣofin to waye.