Yoruba Language: BBC Yoruba ń gbìyànjú kí èdè má parun

Àkọlé fídíò, Ṣé ọ̀rọ̀ yìí ò wa tóbi jù láti túmọ̀ sí Yorùbá?

Ọ̀rọ̀ kìí tóbi títí ká fi ọ̀bẹ bù ú.

Bí a bá jẹ́ ojúlówó ọmọ Yorùbá tí ìmọ̀ èdè wa sì dájú, bí i pé à ń fẹran jẹ̀kọ ló yẹ kí títúmọ̀ èdè Yorùbá jẹ́.

Bí kò bá wá rí bẹ́ẹ̀, ànfàní rèé láti bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ èdè Yorùbá lórí bbc.com/yorùbá.

Ki ede Yoruba ma baa parun ni BBC Yoruba ṣe n ṣeto ibeere nipa 'Bawo lo ṣe gbọ ede Yoruba to?' yii

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Itumó ọrọ Segregation ni ede Yoruba ni: Iyasọtọ, iyọkuro, iyapa yatọ si awọn to ku.

Lilo eyikeyi ninu awọn wọnyii nii ṣe pẹlu asiko ati iru ipo ti a ti loo ninu gbolohun