You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mo Salah: Ajọ agbabọ́ọ́lù Egypt lo àwòrán mi láì gba àsẹ
Agbabọọlu fun orilẹede Egypt ati Liverpool, Mohammed Salah ti fẹsun kan ajọ to n mojuto ere bọọlu alafẹsẹgba ni orilẹede Egypt.
Mo Salah ni ajọ naa kọ lati gba asẹ ni ọwọ oun, ko to di wi pe wọn lo aworan oun lati polongo fun ile isẹ kan.
O fikun wi pe ohun ti ko tọ ni wọn se nitori oun jẹ asoju fun ile isẹ ibaraẹnisọrọ mii ti kii se eleyii ti wọn fun ni aworan oun.
Salah l'oju opo Twitter rẹ ni ohun to buru ni bi ajọ to n mojuto bọọlu alafẹsẹgba l'orilẹede Egypt sẹ kọ eti ikún si iwe ti oun ati agbẹjọro oun kọ si wọn lori aworan rẹ ti wọn lo lọna aitọ.
Amọ, ajọ erebọọlu ti ilẹ Egypt ti kọ jalẹ wi pe ariyanjiyan naa ko le e fa ki Salah ma kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ti Egypt yoo ni pẹlu Niger ni osu to n bọ.