Ọlọ́pàá: Saraki lè kọ èsì ráńṣẹ́ lórí ẹ̀sùn ọ̀hún sí wa

Ọrọ ti bẹ́yìn yọ lataari bi awọn ilé isẹ́ Ọlọ́pàá ti sọ pe awọn kò fi dandan mu Bukola Saraki lati yọju si wọn.

Awọn Ọlọ́pàá ni ki Saraki kọ esi rẹ ransẹ laarin ọjọ meji lọrí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án lánàá.

Ẹsun pe ó lọ́wọ́ nínú ìsẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè Ọfa tó wáyé nínú osù kẹrin ọdún yìí níbí tí wọ́n ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

Sáájú, Saraki sọ pe "mo ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún olùrànlọ́wọ́ mi pé kó gba ìwé ìpeni látọ̀dọ̀ ilé isẹ̀ Ọlọ́pàá èyí tó níi ṣe pẹ̀lú ẹ̀sùn tí wọ́n gbé jáde lánàá kí n lè tètè jẹ́ wọn ní òo".

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ti kọ ìwé jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára wí pé ó ń fẹ́ kí gbogbo ará ìlú kọ etí ikún sí ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tó tún jẹ́ ọàdọ́gbọ́n kó bá ni ní gbogbo ọ̀nà èyí tí ilé isẹ́ ọlọ́pàá rawọ́lé.

Ọkọ̀ Lexus kan tí wọ́n lẹ orúkọ Olórí Ilé Aṣòfin Àgbà, Bukola Saraki, sí wà nínú nkan tí ó dá wàhálà sílẹ̀ tí ó fi di pé ọlọ́pàá orílẹ̀èdè Naijiria yóò máa fa Gómínà Ìpínlẹ̀ Kwara, Abdulfatah Ahmed, létí aṣọ lórí ìdigunjalè Offa.

Ninú ìdáhùn rẹ̀ sí ẹ̀sùn tí ọlọ́pàá fi kàń, Ahmed, sọ wí pé òun kò ṣàtìlẹ́yìn fún àwọn jàǹdùkú kankan o.