Kayọde Fayẹmi: Mo fẹ́ lọ díje fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì

Mínísítà fún ohun àlùmọ́ọ́nì àti ìdàgbàsókè irin tútù, Dókítà kayọde Fayẹmi ti kọ̀wé sílẹ̀ nínú ìgbìnmọ̀ alásẹ ìjọba àpapọ̀.

Ọgbọ̀njọ́ osù kàrùn-un ọdún 2018 ni ìgbésẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni Fayẹ́mí ti kọ̀wé sílẹ̀.

Nígbà tó ń bá BBC sọ̀rọ̀, ọ̀kan lára àwọn tó ń gbẹnu sọ̀rọ̀ fún ààrẹ Muhammadu Buhari, Bashir Hammad ní Fayẹmi kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ láti gbaradì fún ìdíje gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì ni.

Bashir ní ìjọba àpapọ̀ mọ rírì isẹ́ takun-takun tí Fayẹmi se, tí wọn sì gbàdúrà pé kó se àseyọrí nínú àwọn ìdáwọ́lé rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, Kayọde Fayẹmi ló jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó wáyé l'Ékìtì lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Fayẹmi ni òjìlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀rún lé ẹyọ kan ìbò, 941, nígbà tí Ṣẹgun Oni tó ṣe ipò kejì ni ọ̀rìnlénírinwó lé ẹyọkan ìbò.

Òun ni yóò díje dupò gómínà lábẹ́ àbùradà ẹgbẹ́ All Progressives Congress, APC, nínú ètò ìdìbò sí ipò gómìnà tí yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Èkìtì lọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Keje, 2018.

Olùdíje mẹ́tàlélọ́gbọ́n ló kópa ninú ètò ìdìbò nàá.

Lára wọn lati rí gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ nàá, Ṣẹgun Oni.