Africa Eye: Ohun tí ọ̀rẹ́ mi fí sórí 'Social Media' ló wọ̀ mí lójú- Grace

Lori ọrọ ọmọ orilẹede Naijiria ti iwadii ikọkọ ti ileeṣẹ BBC Africa Eye ṣe fi oju rẹ han pe o ṣeese ki ọmọ Naijiria naa, Eddie, 'jẹ balogun ikọ̀ to n ko awọn ọmọ Naijiria lọ ṣe iṣẹ aṣẹwo ni orilẹede India', alaga ajọ to n mojuto ọrọ awọn ọmọ Naijiria to wa nilẹ okeere, Abike Dabiri sọ pe kii ṣe ojuṣe ajọ oun ni lati tọ pinpin iṣẹlẹ naa.

Nigba ti akọroyin BBC kan si, o sọ wi pe ojuṣe ajọ to n gbogun ti ṣiṣe fayawọ ọmọniyan ni Naijiria, NAPTIP ni. Ṣugbọn gbogbo igbiyanju wa lati ba alukoro ajọ NAPTIP sọrọ lo ja si asan.

Fidio naa fi ajọṣepọ to wa laarin awọn aṣẹwo ọmọ ilẹ Adulawọ ti wọn fi New Delhi ṣe ibujoko ni India han.

Ẹka a-ṣe-iṣẹ́ ìwadii ni BBC ṣe iwadii bi awọn ọmọ ilẹ Adulawọ ṣe n di aṣẹwo nilẹ India paapaa ni New Delhi.

Grace to wa lati Nairobi ni Kenya gba lati fọwọsowọpọ pẹlu Africa Eye ki aṣiri gbogbo nkan to n ṣẹlẹ ni ile aṣẹwo naa ni New Delhi le bọ soju araye.

Grace ni ohun ti ọrẹ oun, Goldie fi sori ayelujara lori bi o ṣe n ṣiṣẹ di olowo ni India lo jẹ ki oun kuro ni Kenya wa baa ni India.

O sọ nipa ohun ti oju rẹ ri ni oṣu marun un to fi ṣiṣẹ aṣẹwo ni New Delhi.

Aṣiri bi wọn ṣe n tan awọn ọdọ ọmọbinrin ilẹ Adulawọ lọ ṣiṣe aṣewo kaakiri ilẹ okeere ti n tu ni eyi to yẹ ki awọn ọdọ fi ṣọra nitori pe ohun gbogbo to n dán kọ́ ni wura.