You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Trump di Ààrẹ kẹtàdínláàádọ́ta ti ilẹ̀ America

Ìròyìn bó ṣe n lọ níbi ètò ìbúrawọlé Donald Trump gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Amẹrika

Ìsọníṣókí

  • Lonii ọjọ Aje ni eto iburawọle Donald Trump gẹgẹ bi aarẹ kẹtadinlaadọta orilẹede Amẹrika n waye.
  • Igbakeji ree ti Donald Trump yoo jẹ aarẹ orilẹede Amẹrika lẹyin to ti kọkọ dari orilẹede naa laarin ọdun 2016 si 2020.
  • Donald Trump ti kede lati buwọlu oniruuru igbesẹ lọjọ akọkọ rẹ lọọfiisi gẹgẹ bi aarẹ Amẹrika.
  • Ayẹyẹ eto iburawọle ijọba Donald Trump ko waye ni ita gbangba tori otutu lile.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Joshua Adetunji, Olubayode Alebiosu & Afolabi Akinlabi

  1. Donald Trump di Ààrẹ kẹtàdínláàádọ́ta ti ilẹ̀ America

    Wọn ti bura fun Donald Trump gẹgẹ bii Aarẹ kẹtadinlaadọta fun ilẹ Amẹrika.

  2. Àwọn ààrẹ àná ní Amẹ́ríkà ti wà ní Capitol fún ètò ìbúrawọlé Donald Trump

  3. Trump àti Biden balẹ̀ sí Capitol ṣáájú ètò ìbúrawọlé

    Aarẹ ti ilu sẹsẹ dibo yan, Donald Trump ti balẹ si Capitol bayii, ibi ti eto iburawọle rẹ yoo ti waye.

    O kọwọ rin pẹlu Aarẹ to n kogba wọle, Joe Biden.

  4. Àwòrán láti ibi ètò ìbúrawọlé ààrẹ US, Donald Trumo fún sáà kẹ́rin

    Bi Aarẹ Joe Biden se ki Donald Trump kaabọ ree

  5. Biden kí Trump káàbọ̀ sí llé ìjọba sí White House

    Bi Aarẹ ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan, Donald Trump se n wolẹ si ile ijọba White House niluu Amẹrika ni Aarẹ Joe Biden ki kaabọ pada.

    Awọn olori mejeeji kọ lati pese idahun si ibeere awọn oniroyin saaju ki wọn to wọ White House.

    Ayẹyẹ idakọkọ waye, ti wọn ko si faye gba awọn akọroyin.

    Ayẹyẹ yii lo kọkọ waye ni ọdun 1837 lasiko iṣejọba Aarẹ Martin Van Buren ati Andrew Jackson.

    Ni ọdun 2021, Trump kọ lati wa sibi ayẹyẹ naa nigba ti Biden ransẹ si nitori o si da loju nigba naa pe yoo pada si ipo aarẹ

  6. Donald Trump bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ padà sí White House pẹ̀lú ìṣẹ́ ìsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì

    Donald Trump lọ si ile ijọsin fun isin akọkọ lati ṣe ajọyọ ayẹyẹ ibura wọle sori oye rẹ lọjọ Aje.

    Ijọ St Johns Church ni isin naa ti waye. Bẹẹni isin ọhun ko gba to ọgbọn iṣẹju ti wọn fi pari rẹ.

    Yatọ si Donald Trump ati Iyawo rẹ Melania to wa nibi isin naa, awọn eekan baba olowo bii Mark Zuckerberg to ni Meta iyẹn ileeṣẹ to ni Facebook, Instagram ati Whatsapp pẹlu Jeff Bezos to ni ileeṣẹ Amazon lo wa nibi isin naa.

    Bakan naa ni olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi tẹlẹ, Boris Johnson pẹlu wa nibẹ.

  7. Bí ètò ìbúrawọlé Donald Trump gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ Amẹrika yóò sẹ lọ lónìí rèé

    Aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan Donald Trump yoo pada si White House tii ṣe ileeṣẹ ijọba orilẹede Amẹrika lẹyin ti wọn ba ti bura fun un tan gẹgẹ bi aarẹ kẹtadinlaadọta orilẹede Amẹrika.

    Lara awọn eto ti yoo waye ni ayẹyẹ iburawọle, ọkan o jọkan orin kikọ, yiyan bi ologun ati oriṣiiriṣii awọn eto mii.

    JD Vance to jẹ igbakeji Trump naa yoo ṣe ibura lonii ọjọ Aje ki awọn mejeeji to bẹrẹ ijọba wọn.

    Trump funra rẹ ti ṣeleri lati buwọlu igbesẹ to le ni igba kete ti wọn ba ti ṣe iburawọle fun un tan.

    Awọn ohun to ṣe pataki lati mọ nipa eto iburawọle ọhun niyi.