AFCON 2019: Àwọn olólùfẹ́ Super Eagles fẹ́ kí Rohr tún wọn tò

Awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles faraya lori idije to waye pẹluu Madagascar.

Awọn kan lara wọn gba pe akọnimọọgba wọn, Gernot Rohr n ṣe iṣẹ rẹ daada, nigba ti awọn kan sọ pe ko lo awọn agbabọọlu naa boṣeyẹ ko lo wọn.

Bakan naa ni awọn kan di ẹbi ru awọn agbabọọlu naa. Ọpọ gbagbọ pe awọn kan lara wọn ti dagba ju fun idije naa.

Wọn gba Rohr ni imọran lati maa lo awọn agbabọọlu ‘keekeeke’.

Ọpọ ololufẹ Super Eagles ni inu awọn ko dun si ipa ti wọn kó ninu idije wọn pẹlu Madagascar to jẹ pe igba akkọ ti wọn maa kopa ninu AFCON ni tọdun yii.