You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àyàn: Ti mo bá ti gbọ́ ohùn ìlù ni àárẹ̀ mi máa ń lọ kíá
Iṣẹ́ kíkọ́ àti Èbùn Ọlọrun ni, ó yẹ kí ọmọ Àyàn mọ ìlù lílù nítorí ọmọ Àjànàkú kìí yàrá.
Oluwapamilẹrin Michael Ayanlere to jẹ ọdọmọde tó ń fi ìlù lílù dábírà ni BBC Yoruba fọrọwalẹnuwo lori iṣẹ àyàn.
O ni wọn bi òun sínú ìlù lílù ni.
Ogbéni Oluwaṣẹgun Ayanlakin to jẹ baba ọdọmọde aláyàn yii ni kekere ni Pamilẹrin ti ṣẹnu ṣámúṣámú lori ọrọ ilu lilu.
Ìmọ̀ràn
Pamilẹrin gba àwọn èwe bii tirẹ nimọran láti kọ nipa ẹbun wọn sii ki wọn le di ọga lori talẹnti wọn.
Baba rẹ rọ iran Yoruba lati ma gbagbe orírun wa àti àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀mbáyé ìran kọọkan nitori ọ̀làjú.
'Èyin obi, ẹ fun awọn ọmọ yin laaye lati lo talẹnti wọn, ko sọmọde nibikan mọ́'.
O ni ki wọn tun fún àwọn ọmọ ni ẹ̀kọ́ iwe kika pẹlu.