Coronavirus lockdown Kayeefi: Àkójọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tó yanilẹ́nu lásìkò àjàkálẹ̀ ààrùn Covid-19

Ara ọtọ ni eto Kayeefi BBC ba de l'oṣu yii, nitori pe oriṣiriṣi iṣẹlẹ agbọ damiẹnu la mu wa fun yin.

Bẹrẹ lati ipinlẹ Ọṣun nibi ti awọn ero ile ẹjọ ti deero ẹwọn nitori pe wọn lọ sile ẹjọ lasiko konile-o-gbele to wa lode.

Abi ṣe ti Oluwo ti Iwo, Ọba Abdurasheed Akanbi to sọ pe ki gbogbo aarun coronavirus to yẹ ko ṣe gbogbo ọmọ Naijiria, maa bọ lọdọ oun, ki baba tun to pahun da?

Ka tun sọ ti gomina ipinlẹ Akwa Ibom, to sọ pe ipinlẹ oun ko ni i gba esi ayẹwo coronavirus ti ajọ NCDC gbe jade fun ipinlẹ oun.

Ẹ wo, ẹ jẹ ka sọ diẹ lọrọ ka dakẹ, ẹ f'oju l'ounjẹ ayọ ninu fidio.