Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Wọn ti gbe oku Aarẹ ana, Muhammadu Buhari kuro niluu London lati lọ sin niluu Daura, to wa nipinlẹ Katsina

Ana lo yẹ ki eto isinku naa waye amọ wọn sun si ọjọ Iṣẹgun fun awọn idi kan

Ọjọ Aiku ni Buhari dagbare faye nile iwosan kan niluu London lẹyin aisan ranpẹ

_________________________

Gbọ na, kilode ti a ko ri awọn oniṣẹṣe nibi eto isinkin Awujalẹ ilẹ Ijebu to waja, Ọba Sikiru Kayode Adetona?

Hmmm… bẹẹ la n bini o

Mo gbọ pe awọn oniṣẹṣe yọju lati ṣe ojuṣe wọn, amọ awọn kan ni ko gba wọn laaye lati kopa ninu eto isinku ọhun

Hmmmmm

Sare maa lọ soju opo wa lati mọ ẹkunrẹrẹ iroyin naa

_________________________

Nilẹ Amẹrika

Agbara omi ti gba ibudokọ oju irin abẹ ilẹ, Subway, to wa nillu New York

Iroyin ni ọpọ arinrinajo ni iṣẹlẹ naa ṣe idiwọ fun bi omi ọhun ṣe n wọ inu ọkọ oju irin

Yatọ si ibudokọ oju irin yii, agbara omi tun gba awọn agbegbe mii bii Westchester County ni New York, ati Plainfield ni New Jersy