You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Ẹ dakun ẹ dabọ ẹ boju aanu wo wa
Eyi lawọn ọrọ to gbẹnu awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga fasiti ilu Ibadan
Lasiko iwọde ti wọn ṣe lati fi rawọ ẹbẹ sawọn alaṣẹ ile ẹkọ naa
Pe ki wọn mu adinku ba owo ile ẹkọ naa ti wọn mu alekun ba laipẹ yii
Ṣaaju ni ọpọ akẹkọọ UI n tọrọ owo lori ayelujara lati fi san owo ile ẹkọ
Ajọ INEC ti rọ awọn eeyan ipinlẹ Edo
Lati tuyaya tuyaya jade dibo lọjọ Abamẹta, ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹsan-an
Atẹjade ti INEC fi sori ikanni X wọn lọjọ Ẹti ni anfani tawọn eeyan ni niyi
Lati dibo yan ẹni to ba wu wọn gẹgẹ bi gomina ipinlẹ naa fọdun mẹrin mii
INEC ni kawọn eeyan ba bẹru tabi foya nitori ibo wọn maa ka fun wọn
Ikọ Hezbollah ti ju ado oloro sẹkun ariwa orilẹ ede Israel
Lẹyin ti Israel ju ado oloro lati oju ofurufu si guusu Lebanon
Hezbollah lawọn ibudo ologun lawọn n gbero lati ju ado oloro naa si
Ikọlu yii lo n waye lẹyin ọjọ kan tawọn ẹrọ ibanisọrọ ikọ Hezbollah n bu gbamu mọ wọn lapo