Akomolede ati Aṣa: Kọ́ ẹ̀kọ́ si nípa ààlọ́ nílẹ̀ Yorùbá

Ki lo bọ sodo, ti ko ro tomu? Abẹrẹ ni o.

Eyi jẹ ọkan lara awọn aalọ apamọ to wa nilẹ Yoruba, ti a maa fi n kọ awọn ọmọde ati agba.

Gẹgẹ bi olukọ wa, Nike aya Bankole ti salaye, ọpọlọ ẹni to ba mọ aalọ maa n ji pepe, ti yoo si seranwọ fun ọmọde lati ja fafa.

Bakan naa. Lori eto Akomolede ati Asa lọsẹ yii, olukọ wa tun sọ nipa itan bi aalọ se bẹrẹ, orisi aalọ to wa, itumọ wọn ati ohun ta n lo aalọ fun.

Ẹ wa nnkan fidi le lati kọ ẹkọ siwaju nipa aalọ, kẹ le fi imọ kun imọ yin.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: