You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
LASU Best Graduating Student: Wákàtí kan péré ni mo fi ń kàwé lójúmọ́, èmi kìí ṣe igi ìwé
Yoruba ni ọmọ ti yoo ba jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu samu-samu.
Oladimeji Shotunde, to gba apapọ maaki to ga julọ nile ẹkọ fasiti ipinlẹ Eko, LASU ni akẹkọọ akọkọ ti yoo gba iru maaki to ga bẹẹ ninu itan ileẹkọ naa.
Amọ ohun to ya ni lẹnu julọ ni pe Oladimeji, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni oun ko de ile iyawe-kawe ri lati lọ kawe, ki oun to jẹ akẹkọọ to pegede julọ.
Sotunde, ti baba rẹ jẹ atọkọse, ti iya rẹ si n ta ọja ke ke ke ninu sọọbu kan, fikun pe oun maa n lọ ran baba oun lọwọ lati tun ọkọ se ni sọọbu rẹ.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn Àrọ̀gìdìgbà jẹ́ kí ń rò pé bàbá mi yan Yemọ̀ja ní àlè - Ọmọ Fagunwa
- Ó pé ọdún mẹ́rìnlélàádọ̀ta tí Akintola kú, ìdí abájọ ìja rẹ̀ pẹ̀lú Awolowo rè é
- Ìtàn Gbọnka àti Timi, akọni méjì tó borí Aláàfin Ṣango
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún tí kò bá pín Nàíjíríà sí yẹ́lẹ-yẹ̀lẹ
- Eji Gbadero, ọmọ Ibadan àti jayé-jayé ọmọ ónílẹ̀ ti wọn yẹgi fun l'Eko
- Lisabi Agbongbo Akala rèé, ẹni tó fi ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ gba ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́wọ́ ìmúnisìn
Bakan naa lo tun maa n lọ ẹrọ ata ni owurọ fun iya rẹ to ni ẹrọ ata to fi n pawo wọle, ko to ls sile ẹkọ.
Shotunde ni oun kii se igi iwe nitori wakati kan pere ni oun fi n kawe lojumọ.
O wa gba awọn akẹẹgbẹ rẹ nimọran lati ni isẹ ọwọ kan ni pato yato si iwe, nitori iwe nikan ko to jẹun mọ laye ode oni.