Breastfeeding week 2020: Bí ọyàn ṣe tóbi tàbí kéré sí kò ní ǹkan ṣe pẹ̀lú ìfọ́mọlọ́yàn

Ọsẹ yii ni ayajọ ọjọ ifọmọlọyan lagbaaye oniruuru alakalẹ si ni ajọ eleto ilera ti la kalẹ.

Awọn iyalọmọ ko ni imọ kikun nipa ifọmọlọyan tori ko si iru imọ ti wọn nilo yii larọwọto wọn.

Eyi lo mu ki BBC Yoruba fi ara ọtọ ọn la ṣe igbelarugẹ ti ọdun yii nipa ṣiṣe akojọ fidio yii pẹlu awọn alabiyamọ toju wọn ti ri too nipa asiko ifọmọlọyan.

"Igba ti mo bi ọmọ mi kekere omi kọ, ko jade". Ọpọlọpọ imọran ti wọn gba iya yii, pabo lo ja si.

Abiyamọ́ kan taa ba sọ̀rọ̀ ṣalaye bi ọkan oun ṣe maa n bajẹ bi fifun ọmọ lọyan ko ba lọ deede.

"Ti wọn ba ni lo eleyii maa lo, ti wọn ba ni lo tọhun, ti wọn ba

Ti mo ba fẹ fun ọmọ lọyan ti ọyan yẹn ko ba sẹ, o maa n su mi, igba mi maa sọkun, ara eeyan ko ni balẹ gẹgẹ bii abiyamọ".

Onimọ eto ilera nipa fifun ọmọ lọyan naa sọ awọn ohun tẹ́ẹ gbúdọ mọ nípa kókó orí ọyàn yín lásìkò fífọ́mọlọ́yàn ati bi ẹ ṣe lee gbe ọmọ si aya.

Bakan naa, o ṣalaye lori ohun to maa n fa ki ọyan obinrin da wa silẹ.