Jeremiah Addo: Ọmọ ọdún méjì tó ṣeeṣe kò mọ̀wé jù l'ágbàáyé

Botilẹjẹ wi pe ko fẹsẹ kan ileewe ri, o mọ orukọ ogoji orilẹede ati olu ilu wọn.

Bakan naa lo mọ orukọ awọn aarẹ orilẹede kaakiri agbaye, to fi mọ awọn nkan pataki mi i to n ṣẹlẹ l’agbaye ti ko yẹ ki ọmọ ọdun meji bi tiẹ o mọ.

Baba rẹ, Richard Addo sọ fun BBC pe igba to pe ọmọ ọdun kan ati osṣu mẹẹrin lawọn ti ṣakiyesi pe o tete n mọ nkan. Eyi lo si mu ki wọn o maa kọ ni oriṣiriṣi nkan, ti oun naa si tete n mọ ọ.

‘Koda, ọpọlọ rẹ pe debi wi pe kii gbagbe ohunkohun ti ẹ ba kọ ọ.’’

Akọroyin BBC ṣe idanwo ranpẹ fun lati ọ boya lootọ ni. Iyalẹnu lo si jẹ nigba ti o bẹrẹ si ni i ka oriṣiriṣi nkan.

Baba Jeremiah sọ fun BBC pe nitori pe awọn ko ni owo lọwọ, ọmọ naa ko fi ina mọna-mọna sun ri, tabi wo ẹrọ amohunmaworan ri. Awọn nkan to wa lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ alagbeka lo fi n kọ oriṣiriṣi nkan tuntun.

Ẹbi rẹ n kọ ni imọ sayẹnsi ati iṣiro nitori pe wọn ni igbagbs pe yoo dagba, ti yoo si di ilumọọka onimọ sayẹnsi tabi imọ ẹrọ.