You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Damilọla Ajayi: Ọ̀dá owó ló ṣún mi dé ìdí lílo ìyarun bíi fèrè
Damilọla Ajayi, to n se ohun ara pẹlu lilo iyarun lati fi fọn fere, salaye fun BBC Yoruba pe, orin Fẹla Anikulapo Kuti lo fun oun niwuri lati maa fọn fere.
Damilọla ni ọda owo lo sun oun de idi lilo iyarun lati maa fọn fere si orin Fẹla.
O fikun pe, ibatan oun kan lo kọ oun lati lo nkan miran pẹlu ọra, ki oun si fọn bii fere, ti oun si n lo iyarun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọkunrin to n fọn iyarun bii fere naa ni, lati igba ti wọn ti ya iyarun naa si mimọ ninu ẹgbẹ akọrin nile ijọsin oun, ni ohun gbogbo ti yipada.
Damilọla wa rọ awọn obi lati maa se iwuri fun awọn ohun ara ọtọ, ti awọn ọmọ wọn ba n se, ki wọn ma si lero pe nkan naa ko seese.
O fikun pe laye ode oni, ohun ti aye ko ka si nkankan ni awọn eeyan n tẹwọgba.