You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìbejì Oníbẹ̀mbẹ́ Òru: Owó, ọmọ àbí aya kò leè yà wá
Alhaji Taiwo ati Kehinde Onibẹmbẹ Oru ti pe ẹni ọdun mẹtalelọgọta, amọ ti wọn pa isẹ ọwọ ti wọn kọ ni aarọ ọjọ ti.
Isẹ lilu bẹmbẹ fi ji wéré loru ni wọn yan laayo lati ọjọ pipẹ nilu Ibadan.
Lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba fọrọwerọ, awọn ibeji onibẹmbẹ oru ni, ara adugbo gan mọ awọn papọ pe, to ba di aago mẹta ni oru, ọkan ninu awọn yoo ji lati lọ ri ekeji lati sọrọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Wọn salaye pe ko si ohunkohun to lee ya awọn, tori Ọlọrun lo kọ awọn papọ lati ọrun, olúbi kansoso si lawọn gbe wa saye.
Wọn ni ounjẹ kanna lawọn maa n jẹ ninu ile, aya, ọmọ abi owo ko si lee ya awọn.
Lootọ ni awọn ibeji onibẹmbẹ oru gba pe ede aiyede maa n wa amọ aawọn aarin awọn ko kọja inu ile, tawọn iyawo awọn ko si lee da si.