You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ibadan Poly: Oromidayo Daniel: Mo tú gbogbo ilé Dayo bóya á máa rí ǹkan tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ṣùgbọ́n...
Ẹ̀gbọn Dayo obinrin ku ni ọjọ Abamẹta ni Oromidayo naa ku ni ọjọ́ Aje- A ko mọ ohun to n ṣẹlẹ mọ- Ẹ̀bi Dayo
Ṣé ẹ ranti akẹkọọ ile ẹkọ Gbogbonise ti Ibadan Poly ti wọn ni pe o ku nipasẹ ibalopọ?
BBC Yoruba ti wa ẹbi Oromidayo Daniel kan.
Oro pọ ninu iwe kọbọ ni o.
Wọn ṣalaye ohun ti wọn gabgbọ o ṣẹlẹ ati ipo ti ẹbi naa wa bayii
- "Ogun ló gbé mi lọ sí Central African Republic, àmọ́ ọmọ ni mo gbé bọ̀"
- Òkú mẹ́ta, alàyè márùn-ún lá ti yọ nínú ilé tó wó ní Lagos Island
- Anthony Albanese di olóòtú ìjọba Australia, ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa rẹ̀ rèé
- Àwọn alákatakítí ẹ̀sìn dáná sun ilé mẹ́fà, ṣọ́ọ̀bù méje ní Bauchi lórí ẹ̀sùn sísọ̀rọ̀ òdì sí Islam
- Ta ló gbé òkú ènìyàn sí pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed l'Ekoo? FAAN bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí mẹ́fà lórí ikú "Sound Engineer"
- Ìjọba Eko fún àwọn ọlọ́jà Alaba Rago ní gbèdéke láti fi ibẹ̀ sílẹ̀ fún àtúnṣe
- Àwọn òṣìṣẹ́ DSS gbìyànjú láti dóòlà Deborah, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèrò borí wọn - Gómìnà Tambuwal
Kini ẹ̀bi salaye fun BBC?
Ẹ̀bi Oromidayo Daniel to jẹ akẹkọọ ile ẹkọ Ibadan Poly ti wọn sọ pe o ku lẹyin ibalopo mọkanla ti ba BBC sọrọ.
Wọn ni pe ọdun keje sẹyin ni Baba ati Iya Dayo salaisi.
Bẹẹ ọjọ kẹta lẹyin iku ẹgbọn Dayo obinrin to wa nile ọkọ ni wón tun ranṣe pe wọn pe Dayo naa ti ku sile rẹ ni Ibadan
Won salaye pe wọn ko ri ohunkohun to fihan pe Dayo lo oogun kankan ninu ile rẹ nigba ti wọn tu ibẹ wo finfini.
Ati pe ki awọn eeyan dẹkun isọkusọ ti wọn n sọ pe o ba Aramide ti wọn ba pẹlu rẹ ninu baluwe sun lẹẹmọkanla.
Bakan naa ni wọn mẹnuba pe omo to n tẹramọ iṣẹ ti kii roju rara ni Oromidayo Daaniel jẹ. ati pe akọọlẹ ko ni tase ni ọrọ iku Dayo yii jẹ to si jasi kayeefi fun awọn mọlẹbi.