June 12: Sadik ní àwọn tó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Abacha ní kò kówó jẹ, ó fi pamọ́ fún ìdí kan ni

Ọmọ Ọgagun Sani Abacha ti sọ ohun to mọ nipa iru eniyan ti Baba oun jẹ ni igba aye rẹ.

Lasiko to n ba BBC sọrọ, Ọmọ Abacha ni eniyan daadaa ni Baba oun, to fẹ ki ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ kori.

Bakan naa lo ni awọn eniyan to ba Baba oun ṣiṣẹ ni asiko to wa lori oye sọ pe Baba oun ko lu owo ilu ponpo, ati wi pe ijọba baba oun ko gbogbo eniyan mọra.

Ati pe awọn owo ti wọn ri gba pada naa jẹ awọn owo ti wọn fẹ lo fun awọn nkan miran ni oke okun.

Ẹ wo ẹkunrẹrẹ fidio yii fun awọn ohun miran ti ọmọ Abacha sọ nipa baba rẹ.

Bẹẹ lo ni oun ṣe idaro baba oun nitori to ba wa laye, igbe aye oun yoo dara sii ju bi o ti wa lo.