You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
BB Naija: Ẹgbẹ́ MURIC figbe ta kí ìjọba dá a dúró lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀
Oludari ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ gbogbo musulumi Naijiria MURIC, Ọjọgbọn Ishaq Akintola sọ fun BBC Yoruba pe ẹkọ buruku gbaa ni eto BB Naija ti awọn eniyan n pọnle n kọ awọn ọmọ.
Laipẹ ni ẹgbẹ yii figbe ta ti wọn si fi ọrọ ranṣẹ pe ki aarẹ Muhammadu Buhari fopin si eto agbelewo naa ni kiakia tori pe iwa ibajẹ pọ nibẹ.
Ọjọgbọn yii to jẹ olukọni ni ile iwe giga ti ipinlẹ Eko, LASU jẹ ko di mimọ pe awọn tọrọ ki iwa ibajẹ ma baa gbilẹ lawujọ jẹ lọkan lo kan si awọn kaakiri lati ba wọn gbe ohun soke pe ki ijọba fopin si eto naa.
Ishaq fun 'pe si awọn olori ẹsin lawujọ pe ki wọn ye ba 'ra wọn ja, o tun pe awọn ẹlẹsin Kristẹni, awọn lọba lọba kaakiri Naijiria pe ki gbogbo wọn pawọ pọ ke si ijọba.
Onimọ ẹsin Islam yii ni "fun igbadun ara ile kọ leleyii rara o, igbarun gbaa ni. Ibalu jẹ, ibẹbi jẹ, ibara jẹ, ibadugbo jẹ ni".