Ọọ̀ni: A gbọ́dọ̀ wé láwàní, ká tó jẹ́ Ọọ̀ni

Oníbàjẹ́ ti ba ǹkan jẹ́ sẹ́yìn ṣùgbọ́n alátúnṣe ti de ní ìran yìí- Ọọni

Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ki ẹsẹ̀ Ifá kan délẹ̀ fi ṣalaye bi abẹrẹ to n ṣe ọmọ Yeye Ọ̀bẹ ṣe ṣe.

Ọọnirisa to n ṣọdun ọlọ́jọ́ lọwọ ni ìbàjẹ́ wà laarin àwọn lỌbalỌba àti aṣa Yoruba to ti dorikodo lasiko yii pé o n fẹ́ àtúnṣe.

Bi ọmọ ko ba ba ìtàn, o di dandan kó ba àrọ́bá, Ọba Ogunwusi sọ bi ẹsin Musulumi ati Onigbagbọ ṣe yọ lati ara ẹsin ibilẹ Yoruba.

O sọ nipa ògún- ọ̀ṣọ́ọ̀ṣọ̀ to bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn to wa di ifilọlẹ ìjọ Aguda to bi kátólíìkì loni pẹlu ijọra inu ẹsin Islam pẹlu Oodua to n jẹ Adua.

Àṣà Yorùbá kún fún ẹ̀kọ́ bíi ìkíni, itẹriba, ibọwọfagba àti fifi otitọ inu bá ara ẹni lò pọ̀.