You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aabo to peye gbọdọ wa fawọn olutọju alaisan
Onisegun Oyinbo kan to n sisẹ nile iwosan ẹkọsẹ isegun fasiti Ibadan, taa mọ si UCH, Dokita Kunle Obilade ti kede pe nibi taa ba ti n wo Ọlọkunrun, laa ti n wo ara ẹni, nitori naa, yoo dara kijọba ilẹ wa maa pese ohun eelo aabo to yẹ fawọn olutọju alaisan nile iwosan wa gbogbo lorilẹede yi.